Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 23:21-37 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ẹ pe àpèjẹ mímọ́ ní ọjọ́ náà; ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. Ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún arọmọdọmọ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín títí lae.

22. “Nígbà tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè títí dé ààlà patapata. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè tán, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ gbọdọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

23. OLUWA sọ fun Mose

24. pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́.

25. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kan, ẹ sì níláti rú ẹbọ sísun sí OLUWA.”

26. OLUWA sọ fún Mose pé,

27. “Ọjọ́ kẹwaa oṣù keje ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ní ìpéjọpọ̀ mímọ́ ní ọjọ́ náà, kí ẹ gbààwẹ̀, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

28. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ ètùtù ni, tí wọn yóo ṣe ètùtù fun yín níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

29. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.

30. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, n óo pa á run láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

31. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, ìlànà ni ó jẹ́ títí lae fún ìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín.

32. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀. Ọjọ́ ìsinmi náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsan-an títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹwaa.”

33. OLUWA sọ fún Mose

34. pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, ẹ óo ṣe àjọ̀dún Àgọ́ fún OLUWA; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi ṣe é.

35. Ìpéjọpọ̀ mímọ́ yóo wà ní ọjọ́ kinni, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà.

36. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ óo ní ìpéjọpọ̀ mímọ́, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ìpéjọpọ̀ tí ó lọ́wọ̀ ni, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

37. “Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn.

Ka pipe ipin Lefitiku 23