Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 21:11-24 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Kò gbọdọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n bá tẹ́ òkú sí, tabi kí ó sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú baba rẹ̀ tabi ti ìyá rẹ̀.

12. Kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ninu ibi mímọ́ náà, tabi kí ó sọ ibi mímọ́ Ọlọrun rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí pé, òróró ìyàsímímọ́ Ọlọrun rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Èmi ni OLUWA.

13. Obinrin tí kò bá tíì mọ ọkunrin rí ni ó gbọdọ̀ fẹ́ níyàwó.

14. Kò gbọdọ̀ fi opó ṣe aya tabi obinrin tí ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tabi obinrin tí ó ti mọ ọkunrin, tabi aṣẹ́wó; kò gbọdọ̀ fẹ́ èyíkéyìí ninu wọn. Obinrin tí kò tíì mọ ọkunrin rí ni kí ó fẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

15. Kí ó má baà sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìmọ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé èmi ni OLUWA, tí mo sọ ọ́ di mímọ́.”

16. OLUWA sọ fún Mose,

17. kí ó sọ fún Aaroni pé, “Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ rẹ̀ tí ó bá ní àbùkù kankan kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀.

18. Nítorí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ, kì báà jẹ́ afọ́jú, tabi arọ, ẹni tí ijamba bá bà lójú jẹ́, tabi tí apá tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn ju ekeji lọ,

19. tabi tí ijamba bá ṣe ní ọwọ́ kan tabi ẹsẹ̀ kan,

20. tabi abuké, aràrá, tabi ẹni tí kò ríran dáradára, tabi ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀yi tabi ìpẹ́pẹ́, tabi ẹni tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà.

21. Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ Aaroni, alufaa tí ó bá ti ní àbùkù kan lára kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ sísun sí èmi OLUWA, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ṣì ní àbùkù lára, kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀.

22. Ó lè jẹ ohun jíjẹ ti Ọlọrun rẹ̀, kì báà ṣe ninu èyí tí ó mọ́ jùlọ tabi ninu àwọn ohun tí ó mọ́.

23. Ṣugbọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibi aṣọ ìbòjú náà tabi kí ó wá sí ibi pẹpẹ, nítorí pé ó ní àbùkù, kí ó má baà sọ àwọn ibi mímọ́ mi di aláìmọ́; èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”

24. Mose sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA rán an fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli.

Ka pipe ipin Lefitiku 21