Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 20:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose

2. pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn ati àwọn àlejò, tí wọn ń ṣe àtìpó ní ààrin wọn tí ó bá fi èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, pípa ni kí wọ́n pa á; kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.

3. Èmi gan-an yóo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó ti fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, ó sì ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ó ti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.

4. Bí àwọn eniyan tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà bá mójú fo ẹni tí ó bá fi ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, tí wọn kò pa á,

5. nígbà náà ni èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, n óo sì yọ wọ́n kúrò lára àwọn eniyan wọn, ati òun, ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jọ ń bọ oriṣa Moleki.

6. “Bí ẹnìkan bá ń lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, tabi àwọn oṣó, tí ó sì ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, n óo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

7. Nítorí náà, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

8. Ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn. Èmi ni OLUWA tí ó sọ yín di mímọ́.

9. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀ nítorí pé ó ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀.

10. “Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀ ati obinrin tí ó bá lòpọ̀.

11. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, ó dójúti baba rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

12. Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya ọmọ rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji; wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ láàrin ẹbí, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

13. Bí ọkunrin kan bá bá ọkunrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ bí a ti ń bá obinrin lòpọ̀, àwọn mejeeji ti ṣe ohun ìríra; pípa ni kí wọ́n pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

Ka pipe ipin Lefitiku 20