Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 2:5-15 BIBELI MIMỌ (BM)

5. “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ó fi rúbọ, kí ó jẹ́ èyí tí ìyẹ̀fun rẹ̀ kúnná dáradára, tí a fi òróró pò, kí ó má sì ní ìwúkàrà ninu.

6. Já a sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró lé e lórí, ẹbọ ohun jíjẹ ni.

7. “Bí ẹbọ rẹ bá jẹ́ ti ohun jíjẹ tí a sè ninu ìkòkò, ìyẹ̀fun rẹ̀ gbọdọ̀ kúnná dáradára kí ó sì ní òróró.

8. Gbé àwọn ẹbọ ohun jíjẹ náà wá siwaju OLUWA. Nígbà tí o bá gbé e fún alufaa, yóo gbé e wá síbi pẹpẹ.

9. Alufaa yóo wá bu díẹ̀ ninu ẹbọ ohun jíjẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. Ẹbọ tí a fi iná sun ni, tí ó ní òórùn dídùn tí inú OLUWA sì dùn sí.

10. Ohun tí ó bá ṣẹ́kù ninu ohun jíjẹ náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ni ó mọ́ jùlọ lára ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.

11. “Ẹbọ ohun jíjẹ tí o bá mú wá fún OLUWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà ninu, nítorí pé ìwúkàrà tabi oyin kò gbọdọ̀ sí ninu ẹbọ sísun sí OLUWA.

12. O lè mú wọn wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so oko, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ bí ẹbọ olóòórùn dídùn.

13. Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ rẹ ni o gbọdọ̀ fi iyọ̀ sí, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ wọ́n ninu ọrẹ ohun jíjẹ rẹ; nítorí pé iyọ̀ ni ẹ̀rí majẹmu láàrin ìwọ pẹlu Ọlọrun rẹ, o níláti máa fi iyọ̀ sí gbogbo ẹbọ rẹ.

14. Bí o bá fẹ́ fi àkọ́so oko rẹ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí OLUWA, ninu ṣiiri ọkà àkọ́so oko rẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ni kí o ti mú, kí o yan án lórí iná.

15. Da òróró sí i, kí o sì fi turari sórí rẹ̀. Ẹbọ ohun jíjẹ ni.

Ka pipe ipin Lefitiku 2