Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 16:15-32 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Lẹ́yìn náà yóo pa ewúrẹ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn eniyan Israẹli, yóo sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà, yóo sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù, yóo wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú, yóo sì tún wọ́n ọn siwaju Àpótí Ẹ̀rí.

16. Bẹ́ẹ̀ ni yóo ti ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, nítorí àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli, ati nítorí ìrékọjá ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì ṣe sí Àgọ́ Àjọ tí ó wà láàrin wọn, nítorí àìmọ́ wọn.

17. Kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu Àgọ́ Àjọ nígbà tí ó bá wọlé lọ láti ṣe ètùtù ninu ibi mímọ́ náà, títí tí yóo fi jáde, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, ati ilé rẹ̀, ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli.

18. Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo.

19. Yóo sì fi ìka wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ náà sí ara pẹpẹ nígbà meje, yóo sọ ọ́ di mímọ́, yóo sì yà á sí mímọ́ kúrò ninu àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli.

20. “Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀.

21. Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀.

22. Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ.

23. “Aaroni yóo pada wá sinu Àgọ́ Àjọ, yóo bọ́ àwọn aṣọ funfun tí ó wọ̀ kí ó tó wọ inú ibi mímọ́ lọ, yóo sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.

24. Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà.

25. Yóo sun ọ̀rá ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ náà.

26. Ẹni tí ó fa ewúrẹ́ náà tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀ yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó.

27. Lẹ́yìn náà, wọn yóo gbé òkú akọ mààlúù ati ti òbúkọ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹ̀jẹ̀ wọn tí wọ́n gbé wọ ibi mímọ́ lọ láti fi ṣe ètùtù, wọn yóo rù wọ́n jáde kúrò ní ibùdó, wọn yóo sì dáná sun ati awọ, ati ara ẹran ati nǹkan inú wọn.

28. Ẹni tí ó bá lọ sun wọ́n, yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó wá.

29. “Kí ó jẹ́ ìlànà fun yín títí lae pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje, ati onílé ati àlejò yín, ẹ gbọdọ̀ gbààwẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

30. Nítorí pé, ní ọjọ́ náà ni wọn yóo máa ṣe ètùtù fun yín, tí yóo sọ yín di mímọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ lè jẹ́ mímọ́ níwájú OLUWA.

31. Ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀ ni ó jẹ́ fun yín, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀; ìlànà ni èyí jẹ́ fun yín títí lae.

32. Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà.

Ka pipe ipin Lefitiku 16