Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo fi ìka wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú. Bákan náà, yóo fi ìka wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà siwaju Àpótí Ẹ̀rí nígbà meje.