Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo.