Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 16:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí meji ninu àwọn ọmọ Aaroni kú, nígbà tí wọ́n fi iná tí kò mọ́ rúbọ sí OLUWA, OLUWA bá sọ fún Mose pé,

2. “Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú.

3. Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.

4. “Kí ó kọ́kọ́ wẹ̀, lẹ́yìn náà, kí ó wọ àwọn aṣọ mímọ́ nnì: ẹ̀wù funfun mímọ́, pẹlu ṣòkòtò funfun, kí ó fi ọ̀já funfun di àmùrè, kí ó sì dé fìlà funfun.

5. “Yóo gba òbúkọ meji lọ́wọ́ ìjọ eniyan Israẹli fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.

6. Aaroni yóo fi ọ̀dọ́ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀.

7. Lẹ́yìn náà yóo mú àwọn ewúrẹ́ mejeeji, yóo fà wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

8. Lẹ́yìn náà, yóo ṣẹ́ gègé lórí àwọn ewúrẹ́ mejeeji, gègé kan fún OLUWA, ekeji fún Asaseli.

9. Aaroni yóo fa ẹran tí gègé OLUWA bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

10. Ṣugbọn láàyè ni yóo fa ẹran tí gègé Asaseli bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù lórí rẹ̀, yóo sì tú u sílẹ̀, kí ó sá tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀.

11. “Aaroni yóo fa akọ mààlúù kan kalẹ̀ tí yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀; yóo pa akọ mààlúù náà fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.

12. Lẹ́yìn náà, yóo mú ẹ̀yinná láti orí pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA sinu àwo turari, yóo sì bu turari olóòórùn dídùn tí wọ́n gún, ẹ̀kúnwọ́ meji, yóo sì gbé e lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà.

13. Yóo da turari náà sórí iná níwájú OLUWA, kí èéfín turari náà lè bo ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni má baà kú.

14. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo fi ìka wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú. Bákan náà, yóo fi ìka wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà siwaju Àpótí Ẹ̀rí nígbà meje.

Ka pipe ipin Lefitiku 16