Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 13:8-21 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

9. “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ẹnìkan, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ alufaa lọ.

10. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò,

11. a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ gan-an ni ó wà ní ara ẹni náà. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; kí ó má wulẹ̀ tì í mọ́lé, nítorí pé aláìmọ́ ni.

12. Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan,

13. nígbà náà kí alufaa yẹ olúwarẹ̀ wò, bí àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí bá ti bo gbogbo ara rẹ̀ patapata, kí ó pè é ní mímọ́. Bí gbogbo ara rẹ̀ patapata bá ti di funfun, ó di mímọ́.

14. Ṣugbọn gbàrà tí egbò kan bá ti hàn lára rẹ̀, ó di aláìmọ́.

15. Kí alufaa yẹ ojú egbò náà wò, kí ó sì pe abirùn náà ní aláìmọ́, irú egbò yìí jẹ́ aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀tẹ̀ ni.

16. Ṣugbọn tí egbò yìí bá jiná, tí ojú rẹ̀ pada di funfun, kí ẹni náà pada tọ alufaa lọ.

17. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú egbò náà bá ti funfun, nígbà náà ni kí alufaa tó pe abirùn náà ní mímọ́, ó ti di mímọ́.

18. “Bí oówo bá sọ eniyan lára, tí oówo náà sì san.

19. Bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá wú, tí ó funfun tabi tí ó pọ́n, kí olúwarẹ̀ lọ fihan alufaa.

20. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí wúwú tí ó wú yìí bá jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun rẹ̀ bá sì funfun; kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí oówo.

21. Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, tí wúwú tí ó wú kò sì jìn ju awọ ara olúwarẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

Ka pipe ipin Lefitiku 13