Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 11:27-41 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ninu àwọn ẹranko tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn tí wọ́n sì ní èékánná jẹ́ aláìmọ́ fun yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; ohun àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fun yín.

29. “Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo àwọn ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀ ni: asín, ati èkúté, ati àwọn oríṣìíríṣìí aláǹgbá ńlá,

30. ọmọọ́lé, ọ̀ni, aláǹgbá, agílíńtí ati alágẹmọ.

31. Wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

32. Ohunkohun tí òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, ìbáà jẹ́ ohun èlò igi, tabi aṣọ tabi awọ, tabi àpò, irú ohun èlò yòówù tí ó lè jẹ́, ó níláti di fífọ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn náà, yóo di mímọ́.

33. Bí èyíkéyìí ninu wọn bá jábọ́ sórí ohun èlò amọ̀, gbogbo ohun tí ó bá wà ninu ohun èlò amọ̀ náà di aláìmọ́, fífọ́ ni kí o fọ́ ohun èlò náà.

34. Ohunkohun tí ó bá jẹ́ jíjẹ tí ó bá wà ninu ìkòkò amọ̀ yìí, tabi tí omi inú rẹ̀ bá ta sí lára, di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá jẹ́ mímu, tí ó wà ninu rẹ̀ náà di aláìmọ́.

35. Ohunkohun tí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, kì báà jẹ́ ààrò tabi àdògán, o gbọdọ̀ fọ́ ọ túútúú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

36. Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́.

37. Bí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé orí èso tí eniyan fẹ́ gbìn, èso náà kò di aláìmọ́.

38. Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín.

39. “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

40. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

41. “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 11