Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 26:12-29 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Gbogbo àwọn aṣọ́nà tẹmpili ni a pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. A pín iṣẹ́ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí a ti pín iṣẹ́ fún àwọn arakunrin wọn yòókù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.

13. Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki.

14. Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.

15. Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra.

16. Gègé mú Ṣupimu ati Hosa fún ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ati ẹnu ọ̀nà Ṣaleketi, ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí òkè. Olukuluku àwọn aṣọ́nà ni ó ní àkókò iṣẹ́ tirẹ̀.

17. Àwọn eniyan mẹfa ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ní ojoojumọ, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà àríwá, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà gúsù, àwọn meji meji sì ń ṣọ́ ilé ìṣúra.

18. Fún àgọ́ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn meji sì ń ṣọ́ àgọ́ alára.

19. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari.

20. Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí.

21. Ladani, ọ̀kan ninu ìran Geriṣoni, ní àwọn ọmọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé wọn, ọ̀kan ninu wọn ń jẹ́ Jehieli.

22. Àwọn ọmọ Jehieli meji: Setamu ati Joẹli ni wọ́n ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.

23. A pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Amramu, ati àwọn ọmọ Iṣari, ati àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli.

24. Ṣebueli, ọmọ Geriṣomu, láti inú ìran Mose, ni olórí àwọn tí ń bojútó ibi ìṣúra.

25. Ninu àwọn arakunrin Ṣebueli, láti ìdílé Elieseri, a yan Rehabaya ọmọ Elieseri, Jeṣaaya ọmọ Rehabaya, Joramu ọmọ Jeṣaaya, Sikiri ọmọ Joramu ati Ṣelomiti ọmọ Sikiri.

26. Ṣelomiti yìí ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń bojútó àwọn ẹ̀bùn tí Dafidi ọba, ati ti àwọn olórí àwọn ìdílé, ati èyí tí àwọn olórí ọmọ ogun ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un, ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.

27. Ninu àwọn ìkógun tí wọ́n kó lójú ogun, wọ́n ya àwọn ẹ̀bùn kan sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú ilé OLUWA.

28. Ṣelomiti ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn tí àwọn eniyan bá mú wá, ati àwọn ohun tí wolii Samuẹli, ati Saulu ọba, ati Abineri, ọmọ Neri, ati Joabu, ọmọ Seruaya, ti yà sọ́tọ̀ ninu ilé OLUWA.

29. Ninu ìdílé Iṣari, Kenanaya ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n yàn ní alákòóso ati onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 26