Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 35:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn olóyè náà fi tọkàntọkàn fún àwọn eniyan, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní nǹkan. Hilikaya, Sakaraya ati Jehieli, àwọn alákòóso ninu ilé Ọlọrun, fún àwọn alufaa ní ẹgbẹtala (2,600) ọ̀dọ́ aguntan ati ọmọ ewúrẹ́ ati ọọdunrun (300) mààlúù fún ẹbọ Ìrékọjá.

9. Àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi: Konanaya pẹlu Ṣemaaya ati Netaneli, àwọn arakunrin rẹ̀; ati Haṣabaya, Jeieli, ati Josabadi, àwọn olóyè ninu ọmọ Lefi dá ẹẹdẹgbaata (5,000) ọ̀dọ́ aguntan, ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹẹdẹgbẹta (500) mààlúù fún àwọn ọmọ Lefi kí wọn fi rú ẹbọ Ìrékọjá.

10. Nígbà tí gbogbo ètò ti parí, àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dúró ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí ọba pa.

11. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, àwọn alufaa wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára àwọn ẹran náà sórí pẹpẹ, àwọn ọmọ Lefi sì bó awọ àwọn ẹran náà.

12. Wọ́n ya ẹbọ sísun sọ́tọ̀ kí wọ́n lè pín wọn fún gbogbo ìdílé tí ó wà níbẹ̀, kí wọ́n lè fi rúbọ sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe pẹlu àwọn mààlúù.

13. Wọ́n sun ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Wọ́n bọ ẹran ẹbọ mímọ́ ninu ìkòkò, ìsaasùn ati apẹ, wọ́n sì pín in fún àwọn eniyan lẹsẹkẹsẹ.

14. Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ́jú tiwọn ati ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Nítorí iṣẹ́ ṣíṣe kò jẹ́ kí àwọn alufaa rí ààyè, láti àárọ̀ títí di alẹ́. Wọ́n ń rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń sun ọ̀rá ẹran níná. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi fi tọ́jú tiwọn, tí wọ́n sì tọ́jú ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni.

15. Àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Asafu dúró ní ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Asafu, Hemani, ati Jedutuni, aríran ọba. Àwọn aṣọ́nà tẹmpili kò kúrò ní ààyè wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ti tọ́jú ẹbọ ìrékọjá tiwọn fún wọn.

16. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìsìn Àjọ Ìrékọjá ati ti ẹbọ sísun lórí pẹpẹ OLUWA ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Josaya ọba.

17. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá, wọ́n sì ṣe Àjọ Àìwúkàrà fún ọjọ́ meje.

18. Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu.

19. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya ni wọ́n ṣe Àjọ Ìrékọjá yìí.

Ka pipe ipin Kronika Keji 35