Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu.