Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 31:3-17 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Hesekaya a máa fa ẹran kalẹ̀ ninu agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ sísun ti àárọ̀ ati ti àṣáálẹ́, ati fún ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ẹbọ oṣù tuntun ati àwọn ẹbọ mìíràn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

4. Ọba pàṣẹ fún àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé kí wọ́n mú ọrẹ tí ó tọ́ sí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wa, kí wọ́n lè fi gbogbo àkókò wọn sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn eniyan ní òfin OLUWA.

5. Ní kété tí àṣẹ yìí tàn káàkiri, wọ́n mú ọpọlọpọ àkọ́so ọkà, ati ọtí ati òróró ati oyin, ati àwọn nǹkan irè oko mìíràn wá. Wọ́n tún san ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí wọ́n ní.

6. Àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda tí wọn ń gbé àwọn ìlú Juda náà san ìdámẹ́wàá mààlúù ati aguntan, ati ti àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n kó wọn jọ bí òkítì.

7. Ní oṣù kẹta ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ìdámẹ́wàá náà jọ, wọ́n kó wọn jọ tán ní oṣù keje.

8. Nígbà tí Hesekaya ati àwọn ìjòyè wá wo àwọn ìdámẹ́wàá tí wọ́n kójọ bí òkítì, wọ́n yin OLUWA, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

9. Hesekaya bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn òkítì náà.

10. Asaraya, olórí alufaa, láti ìdílé Sadoku dá a lóhùn pé: “Láti ìgbà tí àwọn eniyan ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn wá sí ilé OLUWA ni a ti ń jẹ àjẹyó, tí ó sì ń ṣẹ́kù, nítorí pé OLUWA ti bukun àwọn eniyan rẹ̀, ni a fi ní àjẹṣẹ́kù tí ó pọ̀ tó yìí.”

11. Hesekaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n tọ́jú àwọn yàrá tó wà ninu ilé OLUWA, wọ́n bá ṣe ìtọ́jú wọn.

12. Wọ́n ṣolóòótọ́ ní kíkó àwọn ẹ̀bùn, ati ìdámẹ́wàá àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà pamọ́. Konanaya, ọmọ Lefi, ni olórí àwọn tí wọn ń bojútó wọn, Ṣimei, arakunrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀.

13. Jehieli, Asasaya, ati Nahati; Asaheli, Jerimotu, ati Josabadi; Elieli, Isimakaya, ati Mahati ati Bẹnaya ni àwọn alabojuto tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Konanaya ati Ṣimei, arakunrin rẹ̀. Hesekaya ọba ati Asaraya olórí ilé OLUWA ni wọ́n yàn wọ́n sí iṣẹ́ náà.

14. Kore, ọmọ Imina, ọmọ Lefi kan tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn tẹmpili ni ó ń ṣe alákòóso ọrẹ àtinúwá tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Òun ni ó sì ń pín àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati àwọn ọrẹ mímọ́ jùlọ.

15. Edẹni, Miniamini, ati Jeṣua, Ṣemaaya, Amaraya, ati Ṣekanaya, ń ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìlú àwọn alufaa, wọ́n ń pín àwọn ẹ̀bùn náà láì ṣe ojuṣaaju àwọn arakunrin wọn, lọ́mọdé ati lágbà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí;

16. àfi àwọn ọkunrin, láti ẹni ọdún mẹta sókè, tí wọ́n ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé ìdílé, gbogbo awọn tí wọ́n wọ ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olukuluku ṣe gbà lójoojúmọ́, fun iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ipò wọn, nípa ìpín wọn.

17. Wọ́n kọ orúkọ àwọn alufaa ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún sókè ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ati ìpín wọn.

Ka pipe ipin Kronika Keji 31