Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 30:9-27 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ OLUWA, àwọn arakunrin yín ati àwọn ọmọ yín yóo rí àánú lọ́dọ̀ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú, wọn yóo sì dá wọn pada sí ilẹ̀ yìí. Nítorí olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní kẹ̀yìn si yín bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ rẹ̀.”

10. Àwọn oníṣẹ́ ọba lọ láti ìlú kan dé ekeji jákèjádò ilẹ̀ Efuraimu ati ti Manase, títí dé ilẹ̀ Sebuluni. Ṣugbọn àwọn eniyan fi wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà.

11. Àfi díẹ̀ ninu àwọn ará Aṣeri, Manase, ati Sebuluni ni wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu.

12. Ọlọrun lọ́wọ́ sí ohun tí àwọn ará Juda ń ṣe, ó fi sí wọn ní ọkàn láti mú àṣẹ tí ọba ati àwọn olórí pa fún wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.

13. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù keji láti ṣe Àjọ Àìwúkàrà.

14. Wọ́n wó gbogbo pẹpẹ oriṣa ati àwọn pẹpẹ turari tí ó wà ní Jerusalẹmu, wọ́n dà wọ́n sí àfonífojì Kidironi.

15. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Ojú ti àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n tètè lọ ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sí ilé OLUWA.

16. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà, gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, eniyan Ọlọrun; àwọn alufaa bẹ̀rẹ̀ sí wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi sí orí pẹpẹ.

17. Àwọn tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́ pọ̀ níbi àpéjọ náà, nítorí náà, àwọn ọmọ Lefi bá wọn pa ẹran wọn kí àwọn ẹran náà lè jẹ́ mímọ́ fún OLUWA.

18. Ogunlọ́gọ̀ eniyan, pataki jùlọ ọpọlọpọ ninu àwọn tí wọn wá láti Efuraimu, Manase, Isakari ati Sebuluni, kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, sibẹ wọ́n jẹ àsè Àjọ Ìrékọjá, ṣugbọn kì í ṣe ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn Hesekaya gbadura fún wọn pé: “Kí OLUWA rere dáríjì gbogbo àwọn

19. tí wọ́n fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni wọ́n fi jẹ àsè àjọ náà gẹ́gẹ́ bí òfin ìwẹ̀nùmọ́ ti ibi mímọ́.”

20. OLUWA gbọ́ adura Hesekaya, ó sì wo àwọn eniyan náà sàn.

21. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pa Àjọ Àìwúkàrà mọ́ fún ọjọ́ meje pẹlu ayọ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ń kọrin ìyìn sí OLUWA lojoojumọ pẹlu gbogbo agbára wọn.

22. Hesekaya gba àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ṣe dáradára ninu iṣẹ́ OLUWA níyànjú. Àwọn eniyan náà jẹ àsè àjọ náà fún ọjọ́ meje, wọ́n ń rú ẹbọ alaafia, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.

23. Gbogbo wọn tún pinnu láti pa àjọ náà mọ́ fún ọjọ́ meje sí i, wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ ṣe é.

24. Hesekaya, ọba fún àwọn eniyan náà ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan láti fi rúbọ. Àwọn ìjòyè náà fún àwọn eniyan ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù, ati ẹgbaarun (10,000) aguntan. Ọpọlọpọ àwọn alufaa ni wọ́n wá, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́.

25. Gbogbo àwọn ará Juda, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn onílé ati àwọn àlejò tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda, gbogbo wọn ni wọ́n kún fún ayọ̀.

26. Gbogbo Jerusalẹmu kún fún ayọ̀ nítorí kò tíì tún sí irú rẹ̀ mọ́ láti ìgbà Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.

27. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n súre fún àwọn eniyan; OLUWA gbọ́ ohùn wọn, adura wọn sì gòkè lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ̀ lọ́run.

Ka pipe ipin Kronika Keji 30