Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 25:8-20 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.”

9. Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?”Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

10. Nítorí náà Amasaya dá àwọn ọmọ ogun Efuraimu tí ó gbà pada sílé wọn. Nítorí náà, inú bí wọn gan-an sí Juda, wọ́n sì pada sílé pẹlu ìrúnú.

11. Ṣugbọn Amasaya fi ìgboyà kó ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀, ó sì pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Seiri.

12. Wọ́n mú ẹgbaarun (10,000) mìíràn láàyè, wọ́n kó wọn lọ sí góńgó orí òkè kan, wọ́n jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, gbogbo wọn sì ṣègbé.

13. Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun.

14. Amasaya kó oriṣa àwọn ará Edomu tí ó ṣẹgun wá sílé. Ó kó wọn kalẹ̀, ó ń bọ wọ́n, ó sì ń rúbọ sí wọn.

15. Inú bí OLUWA sí Amasaya gan-an, ó sì rán wolii kan sí i kí ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń bọ àwọn oriṣa tí kò lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”

16. Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.”Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.”

17. Lẹ́yìn tí Amasaya, ọba Juda, ṣe àpérò pẹlu àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ó ranṣẹ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá, jẹ́ kí á kojú ara wa.”

18. Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀.

19. O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?”

20. Ṣugbọn Amasaya kọ̀, kò gbọ́, nítorí pé Ọlọrun ni ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kí Ọlọrun lè fi Juda lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Edomu.

Ka pipe ipin Kronika Keji 25