Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 23:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún keje Jehoiada alufaa mọ́kàn gírí, ó lọ bá àwọn marun-un ninu àwọn balogun dá majẹmu. Àwọn ni: Asaraya, ọmọ Jerohamu, Iṣimaeli ọmọ Jehohanani, Asaraya ọmọ Obedi, Maaseaya ọmọ Adaya ati Eliṣafati ọmọ Sikiri.

2. Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ kó àwọn Lefi ati àwọn baálé baálé gbogbo ní Israẹli wá sí Jerusalẹmu.

3. Gbogbo wọn pàdé ninu ilé Ọlọrun, wọ́n sì bá ọba dá majẹmu níbẹ̀. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó! Ọmọ ọba nìyí, ó tó àkókò láti fi jọba nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ṣe pé ìran Dafidi ni yóo máa jọba.

4. Ohun tí ẹ óo ṣe nìyí: nígbà tí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi, ìdámẹ́ta ninu wọn yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA,

5. ìdámẹ́ta yóo wà ní ààfin ọba, ìdámẹ́ta tó kù yóo máa ṣọ́ Ẹnubodè Ìpìlẹ̀; gbogbo àwọn eniyan yóo sì péjọ sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Kronika Keji 23