Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 6:4-19 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun;ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!”Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ,ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú!

5. Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru;kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!”

6. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé:“Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀;kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í.Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà,nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀.

7. Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga,bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu.Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀,àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.

8. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà,n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro,ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.”

9. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ,bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè.Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka,bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.”

10. Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́?Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà?Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́.Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn,wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́.

11. Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru,ara mi kò sì gbà á mọ́.”OLUWA bá sọ fún mi pé,“Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba,ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí.Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya,àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́.

12. Ilé wọn yóo di ilé onílé,oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni.Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

13. OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù;láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa,èké ni gbogbo wọn.

14. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná,wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’,nígbà tí kò sí alaafia.

15. Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì.Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

16. OLUWA ní,“Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré,ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́.Kí ẹ lè ní ìsinmi.”Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní,“A kò ní tọ ọ̀nà náà.”

17. Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín.Mo wí fún wọn pé,“Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!”Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.”

18. OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.

19. Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀;n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí,wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn;nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi.

Ka pipe ipin Jeremaya 6