Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 44:15-29 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn,

16. wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA.

17. Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi.

18. Ṣugbọn láti ìgbà tí a ti dáwọ́ ati máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run dúró, tí a kò sì máa ta ohun mímu sílẹ̀ mọ́, ni a kò ti ní nǹkankan mọ́, tí ogun ati ìyàn sì fẹ́ẹ̀ pa wá tán.”

19. Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?”

20. Jeremaya sọ fún gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n dá a lóhùn, lọkunrin ati lobinrin pé:

21. “Ṣebí OLUWA ranti turari tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín, ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà sun ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu, ṣebí OLUWA ranti.

22. OLUWA kò lè farada ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù, ati àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí náà, ni ilẹ̀ yín ṣe di ahoro ati aṣálẹ̀, ati ilẹ̀ tí a fi ń gégùn-ún, tí kò ní olùgbé, títí di òní.

23. Ìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ si yín ni pé ẹ sun turari, ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ kò pa òfin, ati ìlànà rẹ̀ mọ́.”

24. Jeremaya dá gbogbo àwọn eniyan náà lóhùn, pataki jùlọ àwọn obinrin, ó ní, “Ẹ gbọ́ nǹkan tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti,

25. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ̀yin ati àwọn iyawo yín ti fi ẹnu ara yín sọ, ẹ sì ti fi ọwọ́ ara yín mú ohun tí ẹ wí ṣẹ pé, “Dájúdájú a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ sí oriṣa ọbabinrin ojú ọ̀run láti sun turari sí i, ati láti rú ẹbọ ohun mímu sí i.” ’ Kò burú, ẹ mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ!

26. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti: Ó ní, ‘Ẹ wò ó, mo ti fi orúkọ ńlá mi búra pé àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti kò ní fi orúkọ mi búra mọ́ pé “Bí OLUWA ti wà láàyè.”

27. Mo dójúlé yín láti ṣe yín ní ibi. Ibi ni n óo ṣe yín, n kò ní ṣe yín ní oore. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti ni ogun ati ìyàn yóo pa láìku ẹnìkan.

28. Àwọn eniyan díẹ̀ ni wọn yóo sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Ijipti lọ sí ilẹ̀ Juda. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ sí Ijipti yóo wá mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóo ṣẹ, bóyá tèmi ni, tabi tiwọn.

29. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fun yín pé n óo jẹ yín níyà ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ibi tí mo sọ si yín yóo ṣẹ mọ yín lára,

Ka pipe ipin Jeremaya 44