Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 32:8-23 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.

9. Mo bá ra oko náà lọ́wọ́ Hanameli ọmọ arakunrin baba mi, mo sì wọn fadaka ṣekeli mẹtadinlogun fún un.

10. Mo kọ ọ́ sinu ìwé, mo fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́, mo pe àwọn eniyan láti ṣe ẹlẹ́rìí; mo sì fi òṣùnwọ̀n wọn fadaka náà.

11. Mo mú ìwé ilẹ̀ náà tí a ti fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ati ẹ̀dà rẹ̀,

12. mo sì fún Baruku ọmọ Neraya ọmọ Mahiseaya ní èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, níṣojú Hanameli, ọmọ arakunrin baba mi ati níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà, ati níṣojú gbogbo àwọn ará Juda tí wọn jókòó ní àgbàlá àwọn olùṣọ́ náà.

13. Mo pàṣẹ fún Baruku níṣojú wọn pé,

14. ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o mú ìwé ilẹ̀ yìí, ati èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀ tí a sì ká, ati ẹ̀dà rẹ̀, kí o fi wọ́n sinu ìkòkò amọ̀ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́.

15. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé: wọn yóo tún máa ra ilẹ̀ ati oko ati ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’

16. “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé ilẹ̀ náà lé Baruku ọmọ Neraya lọ́wọ́, mo gbadura sí OLUWA, mo ní:

17. ‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ,

18. ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,

19. ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;

20. ìwọ tí o ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ijipti, o sì tún ń ṣe iṣẹ́ náà títí di òní ní Israẹli ati láàrin gbogbo eniyan; o sì ti fìdí orúkọ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.

21. Ìwọ ni o kó àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ, jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu, pẹlu ọwọ́ agbára, ipá ati ìbẹ̀rù ńlá.

22. O sì fún wọn ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn pé o óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.

23. Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!

Ka pipe ipin Jeremaya 32