Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.