Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 2:25-35 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli,má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí,nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́,n óo sì wá wọn kiri.’ ”

26. OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́,bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín,ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín;

27. ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín,tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín;nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi,ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi.Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín,ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là.

28. “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà?Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín!Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda.

29. Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò?Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀!

30. Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni,wọn kò gba ẹ̀kọ́.Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun,bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.

31. Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ.Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli;tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé,‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri;a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’

32. Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀?Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀?Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́.

33. “Ẹ mọ oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí eniyan fi í wá olólùfẹ́ kiri,tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ ti fi ìrìnkurìn yínkọ́ àwọn obinrin oníwà burúkú.

34. Ẹ̀jẹ̀ àwọn talaka tí kò ṣẹ̀, wà létí aṣọ yín;bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bá wọn níbi tí wọ́n ti ń fọ́lé.Gbogbo èyí wà bẹ́ẹ̀,

35. sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́;dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́,nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 2