Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 2:21-31 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́,tí èso rẹ̀ dára.Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata,tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò?

22. Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín,tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀,sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi.

23. Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́;ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali?Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì,kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣebí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀;tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀.

24. Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára,tí ń ṣí imú kiri,nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún.Ta ló lè dá a dúró?Kí akọ tí ó bá ń wá amá wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala,nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó.

25. Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli,má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí,nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́,n óo sì wá wọn kiri.’ ”

26. OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́,bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín,ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín;

27. ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín,tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín;nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi,ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi.Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín,ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là.

28. “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà?Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín!Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda.

29. Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò?Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀!

30. Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni,wọn kò gba ẹ̀kọ́.Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun,bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.

31. Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ.Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli;tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé,‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri;a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’

Ka pipe ipin Jeremaya 2