Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 12:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA ní,“Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́,báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré?Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú,báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani?

6. Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàáati àwọn ará ilé baba rẹti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ;àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ:Má gbẹ́kẹ̀lé wọn,bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.”

7. OLUWA wí pé,“Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀;mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀.Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

8. Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi,ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi;nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

9. Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni?Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni?Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ,ẹ kó wọn wá jẹun.

10. Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀,wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀.

11. Wọ́n sọ ọ́ di ahoro,ilẹ̀ pàápàá ń ráhùn sí mi.Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro,ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún un.

12. Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá,nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà;ẹnikẹ́ni kò ní alaafia,

13. Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè.Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan.Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè,nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.”

14. Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn.

Ka pipe ipin Jeremaya 12