Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 37:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn.

3. Israẹli fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ, nítorí pé ó ti di arúgbó kí ó tó bí i, nítorí náà ó dá ẹ̀wù aláràbarà kan fún un.

4. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù rí i pé baba wọn fẹ́ràn Josẹfu ju àwọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.

5. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lá àlá kan, ó bá rọ́ àlá náà fún àwọn arakunrin rẹ̀, àlá yìí sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i.

6. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ àlá kan tí mo lá.

7. Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.”

8. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bi í pé, “Ṣé o rò pé ìwọ ni yóo jọba lórí wa ni? Tabi o óo máa pàṣẹ lé wa lórí?” Wọ́n sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i nítorí àlá tí ó lá ati nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9. Ó tún lá àlá mìíràn, ó sì tún rọ́ ọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́, mo mà tún lá àlá mìíràn! Mo rí oòrùn, ati òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ mọkanla ní ojú àlá, gbogbo wọn foríbalẹ̀ fún mi.”

10. Nígbà tí ó rọ́ àlá náà fún baba rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Baba rẹ̀ bá a wí, ó ní, “Irú àlá rándanràndan wo ni ò ń lá wọnyi? Ṣé èmi, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ yóo wá foríbalẹ̀ fún ọ ni?”

11. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara rẹ̀, ṣugbọn baba rẹ̀ kò gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, ó ń rò ó ní ọkàn rẹ̀.

12. Ní ọjọ́ kan àwọn arakunrin rẹ̀ ń da agbo aguntan baba wọn lẹ́bàá Ṣekemu,

13. Israẹli bá pe Josẹfu, ó ní, “Ǹjẹ́ Ṣekemu kọ́ ni àwọn arakunrin rẹ da ẹran lọ? Wò ó, wá kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu bá dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

14. Israẹli sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, lọ bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ati ti àwọn agbo ẹran wá, kí o sì tètè pada wá jíṣẹ́ fún mi.” Israẹli bá rán an láti àfonífojì Heburoni lọ sí Ṣekemu.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 37