orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 31 BIBELI MIMỌ (BM)

Ìmọ̀ràn fún Ọba

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ:

2. Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi,ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí.

3. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin,má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́.

4. Gbọ́, ìwọ Lemueli,ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí,àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle.

5. Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin,kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po.

6. Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu,fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle,

7. jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn,kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.

8. Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò,ati ti àwọn tí a sọ di aláìní.

9. Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn.

Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere

10. Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.

11. Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.

12. Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún unkò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13. A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.

14. Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.

15. Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.

16. Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.

17. A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.

18. A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.

19. Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,ó sì ń ran òwú.

20. Ó lawọ́ sí àwọn talaka,a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

21. Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.

22. A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.

23. Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.

24. A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.

25. Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.

26. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.

27. A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.

28. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,

29. “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”

30. Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.

31. Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.