Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 8:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun.

13. Ṣugbọn kò ní dára fún ẹni ibi, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ rẹ̀ kò ní gùn bí òjìji, nítorí kò bẹ̀rù Ọlọrun.

14. Ohun asán kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé yìí, a rí àwọn olódodo tí wọn ń jẹ ìyà àwọn eniyan burúkú, tí eniyan burúkú sì ń gba èrè olódodo, asán ni èyí pẹlu.

15. Ìmọ̀ràn mi ni pé, kí eniyan máa gbádùn, nítorí kò sí ire kan tí ọmọ eniyan tún ń ṣe láyé ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lọ; nítorí èyí ni yóo máa bá a lọ ní gbogbo ọjọ́ tí Ọlọrun fún un láyé.

16. Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti wá ọgbọ́n ati láti wo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní ayé, bí eniyan kì í tíí fi ojú ba oorun tọ̀sán-tòru,

17. mo wá rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun pé, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdí iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Kò sí bí eniyan ti lè ṣe làálàá tó, kò lè rí ìdí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ pé àwọn mọ iṣẹ́ OLUWA, sibẹsibẹ wọn kò lè rí ìdí rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 8