Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 48:28-35 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè Gadi ní ìhà gúsù, ààlà ilẹ̀ náà yóo lọ láti Tamari títí dé ibi àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí dé àwọn odò Ijipti, tí ó fi lọ dé Òkun Ńlá.

29. Ilẹ̀ tí ẹ óo pín láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli nìyí; bẹ́ẹ̀ sì ni ètò bí ẹ óo ṣe pín in fún olukuluku wọn, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

30. Ìwọ̀nyí ni yóo jẹ́ ẹnubodè àbájáde ìlú náà. Apá ìhà àríwá tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta.

31. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Reubẹni, ẹnubodè Juda ati ẹnubodè Lefi. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli ni a fi sọ àwọn ẹnu ọ̀nà ìlú.

32. Apá ìlà oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Josẹfu, ẹnubodè Bẹnjamini ati ẹnubodè Dani.

33. Apá ìhà gúsù tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Simeoni, ẹnubodè Isakari ati ẹnubodè Sebuluni.

34. Apá ìwọ̀ oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Gadi, ẹnubodè Aṣeri ati ẹnubodè Nafutali.

35. Àyíká ìlú náà yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) igbọnwọ (mita 9,000). Orúkọ ìlú náà yóo máa jẹ́, “OLUWA Ń Bẹ Níbí.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 48