Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 46:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ṣugbọn bí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di tirẹ̀ títí di ọjọ́ tí yóo gba òmìnira; láti ọjọ́ náà ni ilẹ̀ náà yóo ti pada di ti ọba. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ni wọ́n lè jogún ilẹ̀ rẹ̀ títí lae.

18. Ọba kò gbọdọ̀ gbà ninu ilẹ̀ àwọn ará ìlú láti ni wọ́n lára; ninu ilẹ̀ tirẹ̀ ni kí ó ti pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má baà gba ilẹ̀ ọ̀kankan ninu àwọn eniyan mi kúrò lọ́wọ́ wọn.”

19. Ọkunrin náà bá mú mi gba ọ̀nà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn, ó bá mú mi lọ sí ibi àwọn yàrá tí ó wà ní apá àríwá ibi mímọ́ náà, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa, mo sì rí ibìkan níbẹ̀ tí ó wà ní ìpẹ̀kun ní apá ìwọ̀ oòrùn.

20. OLUWA wá sọ fún mi pé, “Ní ibí yìí ni àwọn alufaa yóo ti máa se ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ibẹ̀ ni wọn yóo sì ti máa ṣe burẹdi fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọn má baà kó wọn jáde wá sí gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, kí wọn má baà fi ohun mímọ́ kó bá àwọn eniyan.”

21. Ọkunrin náà bá mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, ó mú mi yíká gbogbo igun mẹrẹẹrin gbọ̀ngàn náà, gbọ̀ngàn kéékèèké kọ̀ọ̀kan sì wà ní igun kọ̀ọ̀kan.

22. Ní igun mẹrẹẹrin ni àwọn gbọ̀ngàn kéékèèké yìí wà. Ó gùn ní ogoji igbọnwọ (mita 20), ó sì fẹ̀ ní ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 15) àwọn mẹrẹẹrin sì rí bákan náà.

23. Wọ́n fi òkúta kọ́ igun mẹrẹẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípo. Wọ́n sì kọ́ ibi ìdáná wọn mọ́ ara ògiri.

Ka pipe ipin Isikiẹli 46