Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 44:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ìta ibi mímọ́ tí ó kọjú sí ìlà oòrùn, ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà wà ní títì.

2. OLUWA wí fún mi pé, “Ìlẹ̀kùn yìí yóo máa wà ní títì ni, wọn kò gbọdọ̀ ṣí i; ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé, nítorí èmi OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ti gba ibẹ̀ wọlé. Nítorí náà, títì ni yóo máa wà.

3. Ọba nìkan ni ó lè jókòó níbẹ̀ láti jẹun níwájú OLUWA. Yóo gba ẹnu ọ̀nà ìloro wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.”

4. Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wá siwaju tẹmpili; mo sì rí i tí ìtànṣán ògo OLUWA kún inú tẹmpili, mo bá dojúbolẹ̀.

5. OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé.

6. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olóríkunkun, pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ dáwọ́ àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe dúró.

7. Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́.

8. Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀.

9. “ ‘Nítorí náà, ẹni tí kò bá kọlà ọkàn ati ti ara ninu àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

10. OLUWA ní, “Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada lẹ́yìn mi, tí wọ́n ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn nígbà tí Israẹli ṣáko lọ, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11. Wọ́n lè jẹ́ iranṣẹ ninu ibi mímọ́ mi, wọ́n lè máa ṣe alákòóso àwọn ẹnu ọ̀nà tẹmpili, wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, wọ́n lè máa pa ẹran ẹbọ sísun ati ẹran ẹbọ àwọn eniyan, wọ́n lè máa ṣe iranṣẹ fún àwọn eniyan.

Ka pipe ipin Isikiẹli 44