Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 33:10-29 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé mo gbọ́ ohun tí wọn ń sọ pé, ‘Àìdára wa ati ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí wa, a sì ń joró nítorí wọn; báwo ni a óo ṣe yè?’

11. Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú?

12. “Ìwọ ọmọ eniyan, wí fún àwọn eniyan rẹ pé, bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là, bẹ́ẹ̀ sì ni bí eniyan burúkú bá yí ìwà rẹ̀ pada, kò ní kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní yè nítorí òdodo rẹ̀.

13. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wí fún olódodo pé yóo yè, bí ó bá gbójú lé òdodo ara rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, n kò ní ranti ọ̀kankan ninu ìwà òdodo rẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

14. Bí mo bá sì wí fún eniyan burúkú pé dandan ni pé kí ó kú, bí ó bá yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́,

15. bí ó bá dá nǹkan tí ẹni tí ó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pada, tí ó sì dá gbogbo nǹkan tí ó jí pada, tí ó ń rìn ní ọ̀nà ìyè láì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè; kò ní kú.

16. N kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí o ti dá mọ́. Nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, yóo yè.

17. “Sibẹsibẹ, àwọn eniyan rẹ ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́,’ bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀nà tiwọn gan-an ni kò tọ́.

18. Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

19. Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́, yóo yè nítorí rere tí ó ṣe.

20. Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń wí pé, ‘ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ìwà olukuluku yín ni n óo fi dá a lẹ́jọ́.”

21. Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹwaa ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, ẹnìkan tí ó sá àsálà kúrò ní Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó ní, “Ogun ti kó Jerusalẹmu.”

22. Ẹ̀mí OLUWA ti bà lé mi ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ẹni tí ó sá àsálà náà dé, OLUWA sì ti là mí lóhùn kí ọkunrin náà tó dé ọ̀dọ̀ mi ní àárọ̀ ọjọ́ keji; n kò sì yadi mọ́.

23. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

24. “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli tí ó ti di aṣálẹ̀ wọnyi, ń wí pé, ‘Ẹnìkan péré ni Abrahamu, bẹ́ẹ̀ ó sì gba ilẹ̀ yìí. Àwa pọ̀ ní tiwa, nítorí náà, a ti fi ilẹ̀ yìí fún wa, kí á gbà á ló kù.’

25. “Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín?

26. Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí?

27. “Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta.

28. N óo sọ ilẹ̀ yìí di ahoro ati aṣálẹ̀. Agbára tí ó ń gbéraga sí yóo dópin. Àwọn òkè Israẹli yóo di ahoro tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní gba ibẹ̀ kọjá.

29. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro ati aṣálẹ̀, nítorí gbogbo ìwà ìríra tí wọ́n ti hù.

Ka pipe ipin Isikiẹli 33