“Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta.