Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 23:27-37 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.”

28. OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.

29. Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni

30. ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí o ti bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe àgbèrè, o sì ti fi oriṣa wọn ba ara rẹ jẹ́.

31. Ìwà tí ẹ̀gbọ́n rẹ hù ni ìwọ náà ń hù, nítorí náà, ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ìwọ náà.”

32. OLUWA Ọlọrun ní:“ọpọlọpọ ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ọ́,wọn óo fi ọ́ rẹ́rìn-ín,wọn óo sì fi ọ́ ṣẹ̀sín,nítorí ìyà náà óo pọ̀.

33. Ìyà óo jẹ ọ́ lọpọlọpọ,ìbànújẹ́ óo sì dé bá ọ.N óo mú ìpayà ati ìsọdahoro bá ọ,bí mo ṣe mú un bá Samaria, ẹ̀gbọ́n rẹ.

34. O óo jìyà ní àjẹtẹ́rùn,tóbẹ́ẹ̀ tí o óo máa fi àkúfọ́ àwo ìyà tí o bá jẹ ya ara rẹ lọ́mú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

35. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí pé o ti gbàgbé mi, o sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, o óo jìyà ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ.”

36. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan ṣé o óo dá ẹjọ́ Ohola ati Oholiba? Nítorí náà fi ìwà ìríra tí wọ́n hù hàn wọ́n.

37. Nítorí wọ́n ti ṣe àgbèrè, wọ́n sì ti paniyan; wọ́n ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn, wọ́n sì ti pa àwọn ọmọ wọn ọkunrin tí wọ́n bí fún mi, bọ oriṣa wọn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 23