Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 5:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.”

10. Àwọn tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bá jáde tọ̀ wọ́n lọ, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí Farao ti wí; ó ní òun kò ní fún yín ní koríko mọ́.

11. Ó ní kí ẹ lọ máa wá koríko fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. Ṣugbọn iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò gbọdọ̀ dín!”

12. Wọ́n bá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti wá àgékù koríko.

13. Àwọn tí wọn ń kó wọn ṣiṣẹ́ a máa fi ipá mú wọn pé, lojumọ, wọ́n gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí wọ́n máa ń mọ tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọn kò tíì máa wá koríko fúnra wọn.

14. Àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao bẹ̀rẹ̀ sí na àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Wọn á máa bi wọ́n pé “Kí ló dé tí bíríkì tí ẹ mọ lónìí kò fi tó iye tí ó yẹ kí ẹ mọ?”

15. Àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli bá ké tọ Farao lọ, wọ́n ní, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe báyìí sí àwa iranṣẹ rẹ?

16. Ẹnikẹ́ni kò fún wa ní koríko, sibẹ wọ́n ní dandan, a gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí à ń mọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń lù wá, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ijipti gan-an ni wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”

17. Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ẹ kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ni ẹ fi ń sọ pé kí n jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí OLUWA.

18. Ẹ kúrò níwájú mi nisinsinyii, kí ẹ lọ máa ṣiṣẹ́ yín; kò sí ẹni tí yóo fún yín ní koríko, iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín.”

19. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà ninu ewu, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iye bíríkì tí àwọn ń mọ lojumọ kò gbọdọ̀ dín rárá.

20. Bí wọ́n ti ń ti ọ̀dọ̀ Farao bọ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni tí wọ́n dúró dè wọ́n, wọ́n sì sọ fún wọn pé,

21. “Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.”

22. Mose bá tún yipada sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí o fi ṣe ibi sí àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi rán mi sí wọn?

Ka pipe ipin Ẹkisodu 5