Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 38:3-9 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ó fi idẹ ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ náà: àwọn bíi ìkòkò, ọ̀kọ̀, agbada, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń mú ẹran ati àwo ìfọnná; idẹ ni ó fi ṣe gbogbo wọn.

4. Ó fi idẹ ṣe ayanran ààrò kan fún pẹpẹ náà, ó ṣe é mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀, ayanran náà sì bò ó dé agbede meji sí ìsàlẹ̀.

5. Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.

6. Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.

7. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu.

8. Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

9. Ó ṣe àgbàlá kan, aṣọ funfun, onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni ó fi ṣe aṣọ títa ìhà gúsù àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 38