Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 38:13-29 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Aṣọ títa ti iwájú àgọ́ náà, ní apá ìlà oòrùn gùn ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ.

14. Aṣọ títa fún apá kan ẹnu ọ̀nà jẹ́ igbọnwọ mẹẹdogun, ó ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta.

15. Bákan náà ni aṣọ títa ẹ̀gbẹ́ kinni keji ẹnu ọ̀nà náà rí, wọ́n gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹẹdogun mẹẹdogun, wọ́n ní òpó mẹta mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta mẹta.

16. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ títa tí ó wà ninu àgbàlá náà.

17. Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó rẹ̀; ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, fadaka ni wọ́n yọ́ bo àwọn ìbòrí wọn, fadaka ni wọ́n sì fi bo gbogbo àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

18. Wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró, ati aṣọ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ó gùn ní ogún igbọnwọ, ó sì ga ní igbọnwọ marun-un gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ títa ti àgbàlá náà.

19. Òpó mẹrin ni aṣọ títa tí ẹnu ọ̀nà yìí ní, pẹlu ìtẹ́lẹ̀ idẹ mẹrin. Fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, fadaka ni wọ́n sì fi bo àwọn ìbòrí òpó náà.

20. Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn èèkàn àgọ́ náà, ati ti gbogbo àgbàlá rẹ̀.

21. Ìṣirò ohun tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ ẹ̀rí wíwà OLUWA nìyí: Mose ni ó pàṣẹ pé kí ọmọ Lefi ṣe ìṣirò àwọn ohun tí wọ́n lò lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni, alufaa.

22. Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún Mose.

23. Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, wà pẹlu rẹ̀. Oholiabu yìí mọ iṣẹ́ ọnà gan-an. Bákan náà, ó lè lo aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà.

24. Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

25. Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ.

26. Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550).

27. Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

28. Ninu ẹẹdẹgbẹsan ó lé marundinlọgọrin (1,775) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni ó ti ṣe àwọn ìkọ́ fún àwọn òpó náà, ara rẹ̀ ni ó yọ́ lé àwọn ìbòrí wọn, tí ó sì tún fi ṣe àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

29. Àwọn idẹ tí wọ́n dájọ jẹ́ aadọrin ìwọ̀n talẹnti ati ẹgbaa ó lé irinwo (2,400) ìwọ̀n ṣekeli.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 38