Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 36:21-36 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Gígùn àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

22. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àkànpọ̀ igi náà ní ìkọ́ meji meji láti fi mú wọn pọ̀ mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe gbogbo àwọn àkànpọ̀ igi àgọ́ náà.

23. Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún apá gúsù àgọ́ náà,

24. wọ́n sì ṣe ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka tí wọ́n fi sí abẹ́ ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìkọ́ rẹ̀ mejeeji.

25. Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ mímọ́ náà,

26. pẹlu ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka; ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

27. Wọ́n ṣe àkànpọ̀ igi mẹfa fún ẹ̀yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.

28. Wọ́n sì ṣe àkànpọ̀ igi meji fún igun àgọ́ náà tí ó wà ní apá ẹ̀yìn.

29. Àwọn àkànpọ̀ igi náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn wọ́n so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi òrùka kinni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn àkànpọ̀ igi kinni ati ekeji fún igun mejeeji àgọ́ náà.

30. Àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní igun kinni-keji jẹ́ mẹjọ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrindinlogun, ìtẹ́lẹ̀ meji meji wà lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

31. Wọ́n fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú mẹẹdogun, marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ gúsù,

32. marun-un fún àwọn ti ẹ̀gbẹ́ àríwá, marun-un fún àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn, lápá ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà.

33. Wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú kan la àwọn àkànpọ̀ igi náà láàrin, ọ̀pá náà kan igun kinni-keji àgọ́ náà.

34. Wọ́n yọ́ wúrà bo gbogbo àkànpọ̀ igi náà, wọ́n fi wúrà ṣe ìkọ́ fún àwọn àkànpọ̀ igi náà, wọ́n sì yọ́ wúrà bo àwọn ọ̀pá ìdábùú náà pẹlu.

35. Aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe aṣọ àgọ́ náà, wọ́n sì ya àwòrán Kerubu sí i lára.

36. Wọ́n fi igi akasia ṣe òpó mẹrin, wọ́n sì yọ́ wúrà bò ó. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, wọ́n sì fi fadaka ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹrin fún àwọn òpó náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 36