Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 30:12-19 BIBELI MIMỌ (BM)

12. “Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n.

13. Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.

14. Ẹnikẹ́ni tí a bá kà ní àkókò ìkànìyàn náà, tí ó bá tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ san owó náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA.

15. Bí eniyan ti wù kí ó ní owó tó, kò gbọdọ̀ san ju ìdajì ṣekeli kan lọ; bí ó sì ti wù kí eniyan tòṣì tó, kò gbọdọ̀ san dín ní ìdajì ṣekeli kan, nígbà tí ẹ bá ń san ọrẹ OLUWA fún ìràpadà ẹ̀mí yín.

16. Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.”

17. OLUWA tún wí fún Mose pé,

18. “Fi idẹ ṣe agbada omi kan, kí ìdí rẹ̀ náà jẹ́ idẹ, gbé e sí ààrin àgọ́ àjọ ati pẹpẹ, kí o sì bu omi sinu rẹ̀.

19. Omi yìí ni Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo fi máa fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 30