Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 2:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà, ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Lefi fẹ́ obinrin kan tí òun náà jẹ́ ẹ̀yà Lefi.

2. Obinrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Nígbà tí ó rí i pé ọmọ náà jẹ́ arẹwà, ó gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta.

3. Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò.

4. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.

5. Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà.

6. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.”

7. Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?”

8. Ọmọbinrin Farao dá a lóhùn pé, “Lọ pè é wá.” Ọmọbinrin náà bá yára lọ pe ìyá ọmọ náà.

9. Ọmọbinrin Farao sọ fún ìyá ọmọ náà pé, “Gbé ọmọ yìí lọ, kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, n óo sì san owó àgbàtọ́ rẹ̀ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni obinrin náà ṣe gba ọmọ, ó sì ń tọ́jú rẹ̀.

10. Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó gbé e pada fún ọmọbinrin Farao, ó sì fi ṣe ọmọ, ó sọ ọ́ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí pé láti inú omi ni mo ti fà á jáde.”

11. Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.

12. Nígbà tí ó wo ọ̀tún, tí ó wo òsì, tí kò rí ẹnìkankan, ó lu ará Ijipti náà pa, ó sì bò ó mọ́ inú yanrìn.

13. Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?”

14. Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.”

15. Nígbà tí Farao gbọ́, ó ń wá ọ̀nà àtipa Mose.Ṣugbọn Mose sálọ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó lọ sí ilẹ̀ Midiani, ó sì jókòó lẹ́bàá kànga kan.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 2