Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 13:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.”

3. Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí.

4. Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu.

5. Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun.

6. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ní ọjọ́ keje ẹ óo pe àpèjọ kan fún OLUWA láti ṣe àjọ̀dún.

7. Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 13