Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí.