Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 10:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko.

6. Wọn yóo rọ́ kún gbogbo ààfin rẹ ati ilé gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati ilé gbogbo àwọn ará Ijipti, àwọn eṣú náà yóo burú ju ohunkohun tí àwọn baba ati àwọn baba ńlá yín ti rí rí lọ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dáyé títí di òní olónìí.” Mose bá yipada kúrò níwájú Farao.

7. Àwọn ẹmẹ̀wà Farao sọ fún un pé, “Kabiyesi, ìgbà wo ni ọkunrin yìí yóo yọ wá lẹ́nu dà? Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ kí wọ́n lè lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn. Àbí kò tíì hàn sí kabiyesi báyìí pé gbogbo Ijipti tí ń parun tán lọ ni?”

8. Wọ́n bá mú Mose ati Aaroni pada tọ Farao lọ. Farao ní kí wọ́n lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn, ṣugbọn ó bèèrè pé àwọn wo gan-an ni yóo lọ?

9. Mose dáhùn pé, “Gbogbo wa ni à ń lọ, ati àgbà ati èwe; ati ọkunrin ati obinrin, ati gbogbo agbo mààlúù wa, ati gbogbo agbo ẹran wa, nítorí pé a níláti lọ ṣe àjọ̀dún kan fún OLUWA.”

10. Farao bá dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín bí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín lọ. Wò ó, ète burúkú wà ní ọkàn yín.

11. N ò gbà! Ẹ̀yin ọkunrin nìkan ni kí ẹ lọ sin OLUWA; nítorí pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ fẹ́ àbí?” Wọ́n bá lé wọn jáde kúrò níwájú Farao.

12. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Ijipti, kí eṣú lè tú jáde, kí wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n jẹ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà tí yìnyín kò pa.”

13. Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé.

14. Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 10