Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 10:14-28 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.

15. Nítorí pé wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ojú ọ̀run ṣókùnkùn dudu, wọ́n sì jẹ gbogbo ewé, ati gbogbo èso tí ń bẹ lórí igi, ati koríko tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa. Ẹyọ ewé kan kò kù lórí igi, tabi koríko, tabi ohun ọ̀gbìn kan ninu oko, jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.

16. Farao bá yára pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín ati sí ẹ̀yin pàápàá.

17. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.”

18. Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA.

19. OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

20. Ṣugbọn OLUWA tún mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.

21. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.”

22. Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún odidi ọjọ́ mẹta.

23. Wọn kò lè rí ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì dìde kúrò níbi tí ó wà fún ọjọ́ mẹta. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ wà ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé.

24. Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.”

25. Mose dáhùn pé, “O níláti jẹ́ kí á kó ẹran tí a óo fi rúbọ lọ́wọ́, ati èyí tí a óo fi rúbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun wa.

26. A níláti kó àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ, a kò ní fi ohunkohun sílẹ̀ lẹ́yìn, nítorí pé ninu wọn ni a óo ti mú láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa; a kò sì tíì mọ ohun tí a óo fi rúbọ, àfi ìgbà tí a bá débẹ̀.”

27. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ.

28. Farao bá lé Mose, ó ní, “Kúrò lọ́dọ̀ mi; kí o sì ṣọ́ra rẹ gidigidi, n kò gbọdọ̀ tún rí ọ níwájú mi mọ́; ní ọjọ́ tí mo bá tún fi ojú kàn ọ́, ọjọ́ náà ni o óo kú!”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 10