Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 10:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Farao bá dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín bí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín lọ. Wò ó, ète burúkú wà ní ọkàn yín.

11. N ò gbà! Ẹ̀yin ọkunrin nìkan ni kí ẹ lọ sin OLUWA; nítorí pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ fẹ́ àbí?” Wọ́n bá lé wọn jáde kúrò níwájú Farao.

12. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Ijipti, kí eṣú lè tú jáde, kí wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n jẹ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà tí yìnyín kò pa.”

13. Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé.

14. Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.

15. Nítorí pé wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ojú ọ̀run ṣókùnkùn dudu, wọ́n sì jẹ gbogbo ewé, ati gbogbo èso tí ń bẹ lórí igi, ati koríko tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa. Ẹyọ ewé kan kò kù lórí igi, tabi koríko, tabi ohun ọ̀gbìn kan ninu oko, jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.

16. Farao bá yára pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín ati sí ẹ̀yin pàápàá.

17. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.”

18. Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA.

19. OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

20. Ṣugbọn OLUWA tún mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.

21. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 10