Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 9:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ.

6. Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé, kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń fun yín ní ilẹ̀ dáradára yìí, nítorí pé, olórí kunkun eniyan ni yín.

7. “Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA.

8. Àní, ní òkè Horebu, ẹ mú kí inú bí OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ pa yín run.

9. Nígbà tí mo gun orí òkè lọ, láti gba tabili òkúta, tíí ṣe majẹmu tí OLUWA ba yín dá, mo wà ní orí òkè náà fún ogoji ọjọ́, láìjẹ, láìmu.

10. OLUWA fún mi ní àwọn tabili òkúta meji náà, tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ba yín sọ láti ààrin iná, ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà ni ó wà lára àwọn tabili náà.

11. Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, OLUWA kó àwọn tabili òkúta náà, tíí ṣe tabili majẹmu, fún mi.

12. “OLUWA bá sọ fún mi pé, ‘Dìde, sọ̀kalẹ̀ kíákíá, nítorí pé àwọn eniyan rẹ, tí o kó ti Ijipti wá ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère tí a fi iná yọ́ fún ara wọn.’

13. “OLUWA tún sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí i pé olórí kunkun ni àwọn eniyan wọnyi.

14. Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n pa wọ́n run, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò láyé. N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí yóo tóbi, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.’

15. “Mo bá gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu àwọn tabili òkúta mejeeji tí a kọ majẹmu náà sí ní ọwọ́ mi. Iná sì ń jó lórí òkè náà.

16. Ojú tí n óo gbé sókè, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti yá ère wúrà tí ẹ fi iná yọ́, ẹ ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín.

17. Mo bá mú àwọn tabili mejeeji, mo là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn lójú yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 9