Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 32:33-49 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Oró ejò ni ọtí wọn,àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani.

34. “Èmi OLUWA kò gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá wọn ṣe,ṣebí gbogbo rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ mi?

35. Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san,nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú.Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀,ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá.

36. Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀,nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́,ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn,tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn,kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.

37. Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé,‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà,ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin?

38. Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín,àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí?Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii,kí wọ́n sì dáàbò bò yín.

39. “ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé,èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun,kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi.Mo lè pa eniyan,mo sì lè sọ ọ́ di ààyè.Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́,mo sì lè wò ó sàn.Bí mo bá gbá eniyan mú,kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.

40. Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,mo fi ara mi búra.

41. Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,tí ó ń kọ yànrànyànràn,n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà.

42. Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,yóo sì mu àmuyó.Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,gbogbo wọn ni n óo pa.’

43. “Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA,gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀.Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà,yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”

44. Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni.

45. Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán,

46. ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ.

47. Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.”

48. OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé,

49. “Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli.

Ka pipe ipin Diutaronomi 32