Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 32:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó ní:“Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé.

2. Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò,àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn;kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì,bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára.

3. Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA,àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀.

4. “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín,gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́.Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe,ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.

5. Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i,ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́,nítorí àbùkù yín;ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí.

6. Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí,ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi?Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín,Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀.

7. “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́,ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá.Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín,Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín,wọn yóo sì sọ fun yín.

8. Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè,ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé,gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

9. Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀,ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀.

10. “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn,níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn.Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn,Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀.

11. Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká,láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò,tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọntí wọ́n bá fẹ́ já bọ́,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli.

12. OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀,láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan.

Ka pipe ipin Diutaronomi 32