Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 31:8-18 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA Ọlọrun tìkalárarẹ̀ ni yóo máa ṣiwaju rẹ lọ, yóo sì máa wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí àyà fò ọ́.”

9. Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.

10. Mose bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ní ìparí ọdún keje-keje, ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún ọdún ìdásílẹ̀, ní àkókò àjọ̀dún àgọ́,

11. nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sin OLUWA ní ibi tí ó yàn pé kí wọ́n ti máa sin òun, o gbọdọ̀ máa ka òfin yìí sí etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn.

12. Pe àwọn eniyan náà jọ, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àgbà, ati onílé ati àlejò, tí ó wà ninu ìlú yín, kí wọ́n lè gbọ́, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí wọ́n sì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu òfin yìí.

13. Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ ọ́n lè gbọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ sí òkè odò Jọdani láti gbà.”

14. OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ.

15. OLUWA fi ara hàn wọ́n ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu ninu àgọ́ náà. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà wà ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àgọ́.

16. OLUWA tún sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ àtisùn rẹ kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn eniyan wọnyi yóo lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn ará ilẹ̀ náà ń bọ. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu tí mo bá wọn dá.

17. Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’

18. Láìṣe àní àní, n óo mú ojú kúrò lára wọn ní ọjọ́ náà, nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, nítorí pé wọ́n ti yipada, wọ́n sì ń bọ oriṣa.

Ka pipe ipin Diutaronomi 31