Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 31:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mose tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.

2. Ó ní, “Òní ni mo di ẹni ọgọfa ọdún (120), kò ní ṣeéṣe fún mi mọ́, láti máa fò síhìn-ín sọ́hùn-ún. OLUWA ti wí fún mi pé, n kò ní gun òkè odò Jọdani yìí.

3. OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.

4. Bí OLUWA ti ṣe sí Sihoni ati Ogu, ọba àwọn ará Amori, tí ó pa wọ́n run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí.

5. OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣe wọ́n bí mo ti pa á láṣẹ fun yín ninu òfin tí mo fun yín.

6. Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mú ọkàn gidigidi. Ẹ má bẹ̀rù rárá, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò yín; nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ. Kò ní já yín kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi yín sílẹ̀.”

7. Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́.

8. OLUWA Ọlọrun tìkalárarẹ̀ ni yóo máa ṣiwaju rẹ lọ, yóo sì máa wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí àyà fò ọ́.”

9. Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.

Ka pipe ipin Diutaronomi 31