Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 24:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ;

2. bí obinrin yìí bá lọ ní ọkọ mìíràn,

3. ṣugbọn tí kò tún wu ọkọ titun náà, tí òun náà tún já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì tún tì í jáde kúrò ninu ilé rẹ̀, tabi tí ọkọ keji tí obinrin yìí fẹ́ bá kú,

4. ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kò gbọdọ̀ gbà á pada mọ́ nítorí pé obinrin náà ti di aláìmọ́. Ohun ìríra ni èyí lójú OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

5. “Bí ọkunrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbeyawo, kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ojú ogun tabi kí á fún un ní iṣẹ́ ìlú ṣe, ó gbọdọ̀ wà ní òmìnira ninu ilé rẹ̀ fún ọdún kan gbáko, kí ó máa faramọ́ iyawo rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́.

6. “Bí ẹnikẹ́ni bá yá eniyan ní nǹkankan, kò gbọdọ̀ gba ọlọ tabi ọmọ ọlọ tí ẹni náà fi ń lọ ọkà gẹ́gẹ́ bíi ìdógò, nítorí pé bí ó bá gba èyíkéyìí ninu mejeeji, bí ìgbà tí ó gba ẹ̀mí eniyan ni.

7. “Bí ẹnìkan bá jí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbé, tí ó sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrú, tabi tí ó tà á, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa olúwarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ohun burúkú yìí kúrò láàrin yín.

8. “Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn.

9. Ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Miriamu nígbà tí ẹ̀ ń jáde ti ilẹ̀ Ijipti bọ̀.

10. “Tí ẹ bá yá ẹnìkejì yín ní nǹkankan, ẹ kò gbọdọ̀ wọ ilé rẹ̀ lọ láti wá ohun tí yóo fi dógò.

11. Ìta ni kí ẹ dúró sí, kí ẹ sì jẹ́ kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un wá fun yín.

12. Bí ó bá jẹ́ aláìní ni olúwarẹ̀, aṣọ tí ó bá fi dógò kò gbọdọ̀ sùn lọ́dọ̀ yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 24